Iroyin pajawiri

NCC ti pàsẹ́ fún Iléesẹ́ MTN láti sí àwọn Simu tí wọ́n tí padà

Ojú òpó ìbára ẹni sọ̀rọ̀ Nomba Simu yin gbọdọ̀ ti maa sisẹ́ padà látàri àsẹ tí àjọ NCC pa fún àjọ MTN

Àjọ tó ń mójútó àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ lorileede Nàìjíríà, àjọ NCC ti darí àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ láti ṣí ojú òpó àwọn oníbàárà wọn tí wọ́n ti wọn dena oju opo ila nọ́mbà wọn lópin ọ̀sẹ̀ yìí padà.

Adarí ẹ̀ka ètò ìròyìn àti ọ̀rọ̀ aráàlú fún àjọ naa Reuben Mouka ló kéde àsẹ yìí nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́ja Ajé Monday.

O ṣàlàyé pé àsẹ naa wáyé látàrí ìpalára tí títi àwọn ojú òpó nọ́mbà àwọn èèyàn ti dá sílẹ̀ lẹ́nu ìgbà tí ìgbésẹ̀ náà fi wáyé.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé Monday, ọ̀sẹ̀ yii ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn yabo ẹ̀ka iléeṣẹ́ MTN káàkiri àwọn ìlú yika Nàìjíríà láti mọ ìdí tí wọ́n fi ti ojú òpó ìbánisọ̀rọ̀ wọn àti láti ṣi padà.

Àjọ NCC kọminú pé láti ìgbà tí àwọn ti ń ké sí àwọn ọmọ Nàìjíríà láti so nọ́mbà ìdánimọ̀ wọn pọ̀ mọ́ síìmù wọn, ọ̀pọ̀ ló si kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Wọ́n ní gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kan ni kí wọ́n tètè so nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN wọn papọ̀ mọ́ síìmù wọn ní kété tí wọ́n bá ti ṣi fún wọn padà nítorí tí wọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn tún máa ti nọ́mbà náà padà.

Wọ́n sọ pé ṣíṣí àwọn ojú òpó náà padà jẹ́ ọ̀nà láti fún wọn lanfaani díẹ̀ si láti le so NIN wọn pọ pẹlu nọ́mbà Simu wọn.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti fòntẹ̀ lù ìdájọ́ ikú oloye Ramon Adedoyin latari po lọwọ nínú ikú tó pa Akẹkọọ OAU Timothy Adegoke.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti o fi di kalẹ niluu Akurẹ ti buwọ́lù idajọ iku fun …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *