Awuyewuye lori ọrọ epo nilẹwa Naijiria t’áwọn èèyàn n sọrọ nipa rẹ ati bi ede àìyedè se bẹ silẹ laarin Dangote ati Ajọ NNPC lori ọrọ epo.
Lori awuyewuye naa bi ẹnu ṣe n kun Àjọ NNPC, naa lo n kun alaga ileeṣẹ Dangote Group, Aliko Dangote.
Aawọ, ohun awuyewuye naa ni ko ṣẹyin ọrọ epo bẹntiro to di ọwọngogo nilẹwa Naijiria ati akitiyan ileeṣẹ Dangote lati bẹrẹ si ta epo ti ileesẹ ifọpo rẹ n pese laipẹ yii.
Ṣaaju ni Dangote ti kọkọ sọ pe ileeṣẹ oun yoo bẹrẹ si ta epo ko to di idaji ọdun 2024 ti a wa yii amọ erongba rẹ ko bọ si latari awọn ipenija to n koju.
Oniruru ipenija ni Dangote koju lọna ati ṣaṣeyọri lati bẹrẹ si ta epo naa, lara rẹ ni bo ṣe sun ọjọ ti yoo bẹrẹ si ni ta epo naa siwaju ati bi ijamba ina kan se sọ nileeṣẹ ifọpo rẹ naa.
Amọ ipenija to ga ju ni ariyanjiyan, awuyewuye kan to bẹ silẹ laarin rẹ ati ileese to n se akoso epo bentiroolu nilẹwa Naijiria ìyẹn Àjọ NNPC.
Ohun ti o fa awuyewuye naa ni ọrọ kan to n lọ nigboro pe epo ti ileeṣẹ Dangote n fọ ko dara to eyi ti wọn n ko wọle lati oke okun.
Lọjọ ti wọn ṣi ileeṣẹ ifọpo aladani naa ni Dangote kede pe ida ogun ninu ọgọrun (20%) ipin idokowo ileesẹ naa ni ajọ NNPC ni.
Amọ iyalẹnu lo tun jẹ fun ọpọ ọmọ Naijiria nigba ti iroyin kan tun jade pe iye ipin idokowo ti ajọ NNPC ni nileeṣẹ naa ti dinku bayii lati ida ogun ninu ọgọrun si ida meje ati diẹ ninu ọgọrun 7.2%.
Nibi ipade awọn akọroyin kan ni Dangote funra rẹ ti sọ ọrọ naa nibi to ti sọ pe eyii waye latari pe Ajọ NNPC ko san iye owo to yẹ ko san lasiko lati ni iye ipin idokowo ti wọn fẹnuko si tẹlẹ.
Ṣaaju ni Àjọ NNPC ti kọkọ ra ipin idokowo ida ogun ninu ọgọrun 20% ileeṣẹ naa pẹlu owo ti iye rẹ to $2.76b.
Dangote ni “Ojulowo epo lo n wa lati ileeṣẹ oun, ọpọ epo ti ko dara ni wọn n ko wọ orileede Naijiria lati oke okun”
Lara awọn iroyin mii to n ja rainrain ni pe epo ti Dangote yoo ta faralu ko dara, ati pe tita epo naa jẹ ọna lati jẹ gaba lori gbogbo awọn to n ta epo, ni Dangote n wa.
Ṣugbọn lasiko ti awọn aṣaaju ile aṣojuṣofin ṣabẹwo sileeṣẹ naa to wa lagbegbe Lekki Free Trade Zone, niluu Eko, Dangote ni ọrọ naa ko ri bẹẹ rara.
Lojuna ati fidi rẹ mulẹ pe epo ileeṣẹ naa jẹ olulowo, Dangote ṣayẹwo epo diesel ti wọn ra nile epo meji ọtọtọ ati eyii ti wọn fọ nileeṣẹ rẹ ninu laabu, lati ṣafihan pe oun ko ni ta ayederu epo faraalu.
Lẹyin ayẹwo epo mejeji, o ni ojulowo epo ni yoo wa lati ileeṣẹ oun ati pe ọpọ epo ti ko dara ni wọn n ko wọ ilẹwa Naijiria lati oke okun.
Nibayi Dangote ni “oun ṣetan lati ta ileesẹ oun fun Ajọ NNPC lati maa dari rẹ.
Gẹgẹ bí iroyin ti a gbọ, Dangote ti ni oun ti ṣetan lati ta ileesẹ rẹ naa fun Ajọ NNPC lẹyin awọn awuyewuye to n waye laarin awọn mejeeji.
leeṣẹ iroyin Premium Times jabọ pe Dangote lo sọ ọrọ naa fun oun ninu ifọrọwerọ kan.
Iroyin naa ni Dangote sọ pe “jẹ ki wọn kuku ra ileeṣẹ naa ki wọn maa dari rẹ bi wọn ba ṣe fẹ.
O ni, “Wọn kuku ti pe oun ni ẹni to fẹ jẹ gaba le gbogbo ileeṣẹ epo oun lori, ko si sí wahala….”
O ni “Lati ibẹrẹ ọdun 1970 lati n dojukọ kọ iṣoro epo, ileeṣẹ ifọpo wa le ran ijọba lọwọ lati yanju isoro naa ṣugbọn o da bii pe inu awọn kan ko dun bo ṣe jẹ pe oun ni oun wa ni ipo lati yanju rẹ.
Dangote ni oun ti ṣetan lati fi gbogbo rẹ silẹ, ki Ajọ NNPC kuku ra ileeṣẹ naa ki wọn si maa dari rẹ bi wọn ṣe fẹ.