Oloogbe naa Osi Balogun tilẹ Ibadan, Ọba Lateef Gbadamọsi Adebimpe j’Ọlọhun nipe ni ọjọru Wednesday, ọjọ kẹrinlelogun lẹyin aisan ranpẹ ti wọn lo n se e.
Gẹgẹ bi iroyin naa ti ileesẹ iwe iroyin Naijiria Tribune gbe jade, ologbe naa lo soju Ọba Olubadan tuntun Ọba Owolabi Ọlakulẹyin lasiko sisi Aafin Olubadan tuntun ti o wa ni agbegbe Oke Arẹmọ ni ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan.
Gẹgẹ bi iroyin ọhun ti a gbọ ni pe ayẹyẹ sisi Aafin tuntun naa ni Ori Ade naa ti i se Osi Olubadan tilẹ Ibadan lọ gbẹyin titi di asiko iku rẹ yi.
O ni lati jẹ pe a ti igba naa ni ojojo ti n s’ogun Osi Olubadan naa ti ara Ọba Lateef Gbadamọsi Adebimpe o si le titi ti o fi dipe o waja jẹ’pe Ọlọhun lọjọru Wednesday, ọjọ kẹrinlelogun, osu keje ọdun 2024 yii.
Tori ohun ti a gbọ nipe ologbe naa, Osi Olubadan yi o lanfaani a ti wa nibi ayẹyẹ igb’ọpa asẹ, Olubadan ẹlẹkẹtalelogoji ti o waye ni gbagede Mapo nilu ibadan.