Ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ to wa nipinlẹ Eko, ti gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ to ni ko da bẹẹni ko tọna ki banki apapọ ilẹẹwa Naijiria, CBN, o ma fi ede Arabic kọ nnkan si ara owo Naira ilẹwa Naijiria.
Agbẹjọro kan, Malcolm Omirhobo, lo pe ẹjọ ọhun lọdun 2020 pẹlu awijare pe fifi ede Arabic kọ nnkan si owo lara n tọka si Naijiria gẹgẹ bii orile-ede ẹlẹsin Islam.
O ni eyi si tako ofin to ni orile-ede Naijiria kii ṣe ti ẹlẹsin kan ṣoṣo tabi ẹya kan.
Ṣugbọn ninu idajọ ile ẹjọ lọjọ Iṣẹgun Tuesday ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2024, Onidajọ Yellin Bogoro, sọ pe Omirhobo kuna lati fidirẹ mulẹ pe, erongba CBN jẹ ọna lati sọ Naijiria di ti ẹsin Islam.
Ninu awijare rẹ, Ọgbẹni Omirhobo ṣalaye pe oun ko mọ nnkan ti ede Arabic to wa lara awọn owo Naijiria ti a n na tumọ si.
O ni ki ile ẹjọ paṣẹ fun banki apapọ CBN lati parọ ede naa si ede Gẹẹsi ti o jẹ ede gbogboogbo, tabi si eyikeyi ninu awọn ede Hausa, Igbo tabi ti Yoruba.
Agbẹjọro Omirhobo fẹ ki ile ẹjọ da CBN lọwọkọ lati mase, tẹ tabi pin owo Naira ti wọn ti fi Arabic kọ nnkan si lara mọ
Amọ sugbọn CBN naa pe ẹjọ tako idajọ ile ẹjọ ọhun.
Agbẹjọro banki naa, Abiola Lawal, sọ fun ile ẹjọ pe, ede Arabic to wa lara awọn owo naa ko tii fi igba kankan dunkooko mọ iduro Naijiria gẹgẹ bii orile-ede ti kii ṣe ti ẹlẹsin kan.
Ede Arabic to wa lara owo Naira ko tumọ si ọrọ ẹsin kankan tabi tọka si ibaṣepọ pẹlu ilẹ Arab.
O ni Ijọba amunisin lo fi ede Arabic kọ nnkan si ara owo Naira, fun anfaani awọn ọmọ Naijiria ti ko mọ iwe ka, nitori pe iru awọn eeyan bẹẹ lo pọ ju lasiko ti wọn pa owo Naijiria da si Naira dipo Pọnhun to wa na tẹlẹ.
Ile ẹjọ ti wa da ẹjọ naa nu bayii nitori pe Omirhobo ‘kuna lati fidi awijare rẹ mulẹ pẹlu ẹri ti o daju.