Iroyin pajawiri

Ẹgbẹ́ Emèrè: Olórí Emèrè sàlàyé ìṣepàtàkì ẹgbẹ́ Emèrè láwùjọ.

Ajọdun ẹgbẹ Emere Onitesiwaju ti ọdun yi to waye ni ọjọ Keje osu Kẹjọ ni ile olori ẹgbẹ Emere to wa ni agbegbe orita Sabo niluu Osogbo nipinle Osun dun o larinrin ẹni ba debẹ loleroyin.

Nigba to n sọ iṣepataki ẹgbẹ naa lawujọ, Oyelọla Ẹlẹbuibọn to jẹ olori ẹgbẹ Emere naa sọ pe ẹgbẹ awọn lagbara o si jẹ ẹgbẹ to maa n fi eeyan lọkan balẹ laarin àwùjọ.

Ẹlẹbuibọn ni ”ọmọ ẹgbẹ Emere ki ba wọn bu ìjọba, bẹẹ si ni ọmọ ẹgbẹ Emere ki i se ohun ti ko tọ tabi ohun ibajẹ rara.”

O fikun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ Emere ma n ran ara wọn lọwọ lati le bori ipenija tabi ogun to ba doju kọ wọn.

Olori ẹgbẹ Emere naa tun tesiwaju ninu ọrọ rẹ pe, bi ẹni to ba ni ẹmi Emere ko ba ti jẹ nkan ewọ ko le ku ni kekere.

Eyi tako igbagbọ ọpọ eeyan ti wọn maa n sọ pe awọn ọmọ Emere maa n ku iku aitọjọ

Oyelola ni awọn ti awọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Emere, Ọlọrun maa n gbọ adura awọn gidigidi ni gbogbo igba ti awọn ba ti gbadura si Ọlọrun.”

O wa gba gbogbo eeyan nimoran wi pe, ki wọn ni ifẹ ọmọ ẹnikeji wọn daada, ki wọn le bori isoro to n doju kọ ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ati eyi to n doju kọ orile-ede Naijiria lọwọ yii.

Ẹgbẹbunmi Ifawuyi to jẹ akowe fun ẹgbẹ naa sọ wi pe, ko si ẹni ti ko ni ẹgbẹ sugbọn o le yàtọ̀ sira wọn ni.

Ẹgbẹbunmi ni, akọsilẹ ti wa fun olukaluku lati ode ọrun wa, o ni awọn ọmọ ẹgbẹ Emere ti oun mọ, wọn dagba wọn si di ogbo ki wọn to pa ipo da.

”Bi ọmọ ẹgbẹ Emere ba tọju ẹgbẹ daadaa yoo pẹ laye gidigidi a si tun ni owo lọwọ, tori ẹgbẹ Emere jẹ ẹgbẹ to ni alubarika lọpọlọpọ.

O ni, Nigba ti oun darapọ mọ ẹgbẹ Emere ni aye oun dara,

O tun fi kun ọrọ rẹ wi pe ẹni to ba tọju ẹgbẹ Emere yoo pẹ laye nitori ẹgbẹ yoo mọ fi ọdun kun ọjọ aye rẹ.

Ọpọlọpọ awọn oyinbo aláwọ̀ funfun lo peju pesẹ si bi ajọdun ẹgbẹ Emere nas to waye nilu Osogbo l’ọdun yii.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ọ̀dájú Ọkùnrin kan dáná sun ìyàwó rẹ̀ lásìkò tí wọn n ja.

Ọkunrin kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Nwanna ni abule Abagana nipinlẹ Anambra …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *