Iroyin pajawiri

Davido àti Chioma s’ègbéyàwó nísu lọ́kà, ò dùn, ó lárinrin Chivido 2024 ni wọ́n n pe àkọlé ayẹyẹ ìgbéyàwó náà.

Ọjọ Iṣẹgun Tuesday, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yi ni ayẹyẹ igbeyawo naa waye laarin gbajugbaja ilumọnka olorin takasufe, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido, ati afẹsọna rẹ, Chioma Rowland.

Ṣaaju ikede ayẹyẹ igbeyawo naa ni iroyin kan ti saaju gbe jade pe Chioma ati Davido ti ṣe igbeyawo wọn ọhun ni nkan bi ọdun kan sẹyin.

Eyi jẹyọ ninu ọrọ ti Davido sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe ninu oṣu Kẹta pe, oun ti gbe Chioma niyawo.

Asiko ti ololufẹ mejeeji ọhun fi wa ni isinmi, lẹyin iku ọmọ wọn ti okiki iku rẹ kan nigba kan Ifeanyi Adeleke ni o ni igbeyawo naa waye.

Se lati ọdun 2018 ti Davido ti kede to si ti ṣafihan Chioma gẹgẹ bi ololufẹ rẹ, iyawo afẹsọna ni aye ti n fojusọna ọjọ igbeyawo wọn.

Si safihan Chioma gẹgẹ bi afẹsọna rẹ ọhun jẹyọ ninu orin rẹ kan ti o pe akọle rẹ ni Assurance’, lati igba naa ni iroyin kosi ti dawọ duro lori ifẹ wọn.

Bẹẹni awọn ololufẹ mejeeji naa kii tẹti tiju ati fi ifẹ wọn han si araye ni gbangba.

Davido ti figba kan sọ ninu ifọwanilẹwo pe, o ti to ogun ọdun ti oun ti mọ Chioma, saaju ki wọn o to pade nigba to wa ni ipele akọkọ nilewe giga fasiti.

Ni Ọdun 2013 ni irinajo ifẹ wọn bẹrẹ ti ina ifẹ naa si n jo wẹrẹwẹrẹ lati igba naa.

“Igbesẹ to dara julọ ti mo ti i gbe ni fifẹ Chioma.”

Ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2019, ni Davido kede pe awọn ẹbi awọn ti mọra wọn.

Ninu oṣu Kẹwaa ọdun naa si ni wọn bi akọbi ọmọ wọn, Ifeanyi, botilẹ jẹ pe Davido ti bi ọmọ meji tẹlẹ. Amọ, ibanujẹ wọ inu ile ololufẹ mejeeji ọhun nigba ti ọmọ wọn ku nigba naa.

Inu odo iwẹ igbalode ti wọn npe ni swimming pool to wa ninu ile wọn ni ọmọ naa bọ si ti o ti mu omi yo.

Iku ọmọ waye lẹyin oṣu kan ti wọn sẹ ọjọ ibi ọdun mẹta rẹ.

Lẹyin iku ọmọ wọn naa ọpọlọpọ oṣu ni awọn mejeeji ko fi yọju si gbangba, yala lori ayelujara tabi si igboro.

Ninu oṣu Kejila ni awọn mejeeji to yọju sita ni Qatar ti Davido ti kọrin nibi idije agbaye ọdun 2022.

O ku diẹ ko pe ọdun kan ti ọmọ wọn naa ku ni iroyin kan gbe gbe pe Chuoma bi ibeji pupọ awọn eeyan ni wọn kofi bẹ gba iroyin naa gbọ.

Afigba ti Davido fun ra rẹ kede pe awọn bi ibeji ni orilẹede America.

Itan tuntun miran ni wọn tun ti wa fi balẹ bayi pẹlu bi wọn ti se igbeyawo alarinrin eyi ti aye gbọ ti ọrun pẹlu naa si mọ

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti fòntẹ̀ lù ìdájọ́ ikú oloye Ramon Adedoyin latari po lọwọ nínú ikú tó pa Akẹkọọ OAU Timothy Adegoke.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti o fi di kalẹ niluu Akurẹ ti buwọ́lù idajọ iku fun …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *