Iroyin pajawiri
{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":false,"containsFTESticker":false}

Nítorí ẹran Iléyá Pásítọ̀ àt’àwọn ọmọ ìjọ, lu Alfa àti àwọn ẹlẹ́hàá rẹ̀ níli Ìsẹ́yìn.

Alfa Sulaiman Abdulazee ati awọn iyawo rẹ Ẹlẹhaa meji ni wọn ti dero ile iwosan lẹyin ti ede-aiyede bẹ silẹ laarin wọn ati Olusọ aguntan ti wọn mule ti.

Iṣẹlẹ naa lo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kefa, ọdun 2024, eyi tii ṣe ọjọ ọdun Ileya, ni agbegbe Barracks, Odo Omu, nilu Iseyin nipinlẹ Oyo.

Iroyin naa to tẹ wa lọwọ ni pe kete ti Alfa Abdulazeez kuro ni irun yidi, ti wọn dari pada si ile pa ẹran ọdun, ni wahala naa bẹ silẹ.

Ọrọ naa lo ti di tile ẹjọ bayi ti Agbẹjọro fun Alfa Abdulazeez, Amofin A.A Olowonjaye si ṣalaye pe lati bii ọdun mẹrin sẹyin ni ede aiyede ti n waye laarin onibaara oun ati Pasitọ Busari Stephen.

“Ni agbegbe Barracks Odo Omu niluu Iseyin ni Alfa Abdulazeez kọ ile si, lẹyin ọdun marun un ni Pasitọ Burasi naa wa mu ile ti wọn, to si n lo o lati fi se ile ijọsin.

“Eyi ko mu wahala da ni nitori Alfa ba awọn Ile ijọsin meji mii ladugbo naa sugbọn ojoojumọ ni Pasitọ Busari n ṣe ijọsin pẹlu ariwo ti ko se farada, laarọ, lọsan ati alẹ.

“Ariwo ọhun lo n bi awọn ara adugbo ninu sugbọn nitori ile Pasitọ naa wa niwaju ile Alfa, iyẹn mu ki ariwo naa pọ pupọ to si n daamu Alfa ati awọn Ẹlẹha rẹ

Ni nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin, ni wọn kọ lẹta si Pasitọ Busari lori ariwo naa pe ko gbiyanju lati mu adinku ba tabi ki wọn dari rẹ si bi ti ko ni daamu awọn ara adugbo sugbọn ti Pasitọ naa kọjalẹ.”

Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye o ni eyii to bi ija to sẹsẹ bẹrẹ bayii ni eyi to waye lasiko ọdun Ileya nigba ti onibaara oun Mallam Abdulazeez pada de lati Mọṣalasi ni ọjọ ọdun Ileya, to si gbe ẹran agbo sita lati pa ni ilana ẹsin Islam lori ilẹ rẹ.

O ni eyi lo di ariwo ti Pasitọ sọ fun Alfa pe ko lẹtọọ lati kọju ẹran pipa si ọna ile ijọsin oun.

O tẹsiwaju pe Pasitọ naa kesi ọmọ rẹ, Damilola, to jẹ ọmọ ologun orilẹede Naijiria, ti wọn si yawọ ile Alfa lati lu u ni alubami pẹlu awọn iyawo rẹ meji, ti ọkan wa ninu oyun.

“Nitori pe ọjọ naa jẹ ọjọ Aiku Sunday ti awọn Pasitọ naa n se isin wọn lọwọ lo mu ki o ribẹ.

Pasitọ jade lati inu ile ijo̱sin rẹ lọ ba Alfa nibi to ti n pa ẹran, pe ki lo de to fi nda oju pipa ẹran kọ iwaju ile ijọsin oun.

“Alfa naa si da l’oun pe o ilana bi wọn se maa n pa ẹran ninu ẹsin Islam ati pe ori ilẹ oun ni oun wa.

“Ọrọ yii ko ju bẹ lọ, ti Pasitọ fi leri si Alfa ti kosi ju nkan bi isẹju diẹ, ti Pasitọ naa fi kesi ọmọ rẹ kan to jẹ Soja, ti wọn pe orukọ rẹ ni Damilola Stephen nigba to n bọ, o kesi awọn Soja akẹgbẹ rẹ ti orukọ wọn n jẹ, Blessing Olusesi ati Azeez Taofeek.

“Lẹyin naa ni ọkan lara wọn ti kii ṣe ọmọ ologun pẹlu Pasitọ yabo ile Alfa pẹlu igi, apola, irin, ọbẹ lọwọ wọn.

“Eeyan marun un ti ki i se Sọja, pẹlu Soja mẹta lo lu Alfa, bi wọn se n lu ni wọn n saa, ti wọn si tun ti i ṣubu.”

Olowonjaye n tẹsiwaju wipe, bi wọn ṣe n lu Alfa ni awọn iyawo rẹ meji jade sita si wọn, ti awọn ẹlẹha naa si tun jade siya lọwọ awọn eeyan ti Pasitọ pe wa

“Lilu naa kosi to wiwọ eeyan marun lori eeyan kan ni awọn iyawo alfa to jẹ ẹlẹha npa ti wọn ṣe sare sita pe ki wọn ma lu Alfa mọ.

“Lilọ ti iyawo to loyun sinu lọ sibẹ, lasiko igbati awọn ọmọ ọmọ ijọ naa ti jade lo jẹ ki o farapa gan an, to si ti dero ile iwosan bayi.

Gẹgẹ bi wọn ti wi nigba ti wọn de ile iwosan, wọn ni oyun obinrin naa ti farapa, ti wọn si n gbadura pe ki ọmọ naa ma ku.

Bakan naa ni wọn tun ti jẹki o di mimọ pe awọn eeyan Pasitọ ọhun fọ gi mọ iyawo kekere alfa lori, ti ori rẹ si bẹ.

Olowonjaye ni awọn eeyan Pasitọ ko gba awọn eeyan Alfa laaye lati fi foonu wọn ka gbogbo nnkan to waye, ti wọn si n dunkoko mọ wọn sugbọn wọn ri diẹ ka.

Ko pẹ ti wọn wa ni ile iwosan ni wọn tun gbọ pe wọn tun ti yabo ile alfa lati kọlu awọn eeyan to n ran Alfa lọwọ lati pa ẹran.

“Wọn gun eeyan kan lọbẹ, to si fi ọwọ gba nitori wọn gbe ọkunrin naa lọ sugbọn o kọ jalẹ.

Olori fun ẹgbẹ CAN niluu Iseyin, Olusọ Aguntan Ogundairo Adeniyi sọ pe awọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa ti awọn si ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ alaafia lori rẹ.

Bakan naa, Adeniyi ni CAN ti fofin de pasitọ naa pe ko gbe ile ijọsin rẹ kuro ni agbegbe naa ni kiakia.

Alaga fun ẹgbẹ CAN sọ pe nigba ti oun de gẹgẹ bi Alaga CAN ni ijọba ibilẹ Iseyin, oun ri pe Pasitọ lo kọja aye rẹ, nitori ko gba ifẹ laaye ati pe kii se iwaju ile ijọsin rẹ ni Alfa ti n pa ẹran.

O ni oun ti lọ kaakiri ọdọ awọn ti ọrọ kan, o ni oun lọ si ọdọ awọn Alfa niluu Isẹyin lati petu si ija naa.

Amọ ju gbogbo ẹ lọ o ni awọn ti fofin de Pasitọ pe ko gbe Ile ijọsin rẹ kuro ni agbegbe naa fun alaafia ati fun ẹmi ara rẹ gan-an.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ọ̀rọ̀ akọ àti abo tí Trump sọ nípa rẹ̀ kò kàn èmi o torí obìnrin ni mí, mo sì ní ẹ̀rì tó dájú – Bobrisky

Ọ̀rọ̀ akọ àti abo tí Trump sọ nípa rẹ̀ kò kàn èmi o torí obìnrin …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *