Iroyin pajawiri
{"remix_data":[],"remix_entry_point":"challenges","source_tags":["local"],"origin":"unknown","total_draw_time":0,"total_draw_actions":0,"layers_used":0,"brushes_used":0,"photos_added":0,"total_editor_actions":{},"tools_used":{"addons":1,"transform":1},"is_sticker":false,"edited_since_last_sticker_save":true,"containsFTESticker":false}

Náwó náwó e s’àpà o, o ni ẹ̀gùn to n maa n gun ìran Yorùbá to ma n m’ori wa wú láti náwó lágbo, Oluwo si àjọ EFCC.

Náwó náwó e s’àpà o, o ni ẹ̀gùn to n maa n gun ìran Yorùbá to ma n m’ori wa wú láti náwó lágbo, Oluwo si àjọ EFCC.

Oluwo tilu Iwo, Oba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọrọ nipa awuyewuye ọrọ to n lọwọ yi ti o niise nipa ẹsun titabuku owo Naira ilẹwa ti ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu sise owo ilu kumọ kumọ iyẹn ajọ EFCC.

Gẹgẹ bi Ọba alaye naa se sọ, o ni owo nina loju agbo tabi lode ariya wa ninu asa iran Yoruba ati ẹya Igbo, Oluwo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan ti o ti ọwọ akọwe iroyin rẹ Ali Ibarahim jade lọjọru Wednsday

O ni nkankan wa ti a n pe ni ẹ̀gùn ninu ẹya Yoruba ti o jẹ pe a maa muniyan nawo kọja bi o ti yẹ lasiko ti inu rẹ ba n dun lode ariya, amọ ti ilani lọyẹ bati wa pe ijiya nbẹ fun ninawo bi ẹlẹda, titabuku ba owo naira ti eeyan ba ti ni imọlara yi yoo kora ro lati se bẹ loju agbo.

Se, ilu ti o si ofin ẹsẹ o si nibẹ, amọ ni kete ti ofin bati wa awọn eeyan ilu yoo kora wọn ni ijanu ati maa dẹsẹ.

Oluwo wa nawọ imọran si ajọ EFCC pe ki wọn o se ilani lọyẹ, idanilẹkọ bi a ti sowo Naira laini tako ofin ilana ti o rọ mọ ati awọn ijiya ti o ba wa nibẹ.

O ni ki wọn o jẹ ilani lọyẹ naa o waye saaju ki wọn o to maa fọwọ lile mu awọn eeyan.

O sọ fun awọn ajọ naa pe ki wọn o fi kun suuru wọn, ki wọn o se pẹlẹ, ki wọn o fi kun igbiyanju wọn lori ati maa se ilani lọyẹ saaju ijiya.

O wa tun gboriyin fun ajọ EFCC lori igbiyanju wọn pẹlu bi wọn ti n fọwọ ofin mu awọn to n kowo ilu jẹ ti wọn n sowo ilu kumọkumọ.

Oluwo tun wa sate̱mọ rẹ pe bi iran Yoruba ati ẹya igbo se ma n nawo lode ariya niise pẹlu asa wọn, o ni ẹgun ti o maa n gun wọn ajaja bi wọn ba n ki wọn loju agbo niise lori wọn a maa wu ti wọn o si maa nawo bi pe awọn ni wọn tẹwo naa jade amọ bi ajọ EFCC bale se lani lọyẹ jẹ awọn eeyan o mọ iru ijiya ti o wa fun ẹni ba nawo bi ẹlẹ́dà ti o nawo nina abuku yoo foju wina ofin, onikaluku yoo koraro sunraki.

O ni bi wọn ba mọ pe fifoju bale ẹjọ, fifẹwọn gbara tabi sisanwo itanran wa fun ẹni ba tabuku owo naira, bi o ti wu ki wọn kiyan ki ori owu, koni fẹwọn gbara yoo se pẹlẹ.

Nitori naa ki ajọ EFCC o gbe igbiyan wọn lori ilanilọyẹ saaju fifọwọ lile mu awọn eeyan

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ìmáàmù Agba Ogbomoso tu ba o, o rawọ-ẹbẹ sí Sọun tilẹ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlabi, pe ko má bínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ t’oun bá ṣẹ̀

Lẹyin ọpọ awuyewuye, gbonmisi-omi-o-t o ti waye fun igba pipẹ laarin Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *