Ìyá àgbà ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni Muniratu Bilewu ni ilu Saki ni agbegbe oke ogun, ni ipinlẹ Ọyọ ni wọn lo ti pada jade laye bayi o.
Iya agba ẹni ọdun Mẹ́rìndínlígba naa ni wọn lo ti logba pẹlu Ọba Ọkẹrẹ ti ilu Saki bi mẹtadinlogun 17, ọpọ awọn ọba naa ni wọn ba laye ti wọn si tun fi s’aye lọ.
Ọpọ eeyan lẹnu n ya ti wọn si nkọ ha lori ọjọ ori iya agba naa pe njẹ ẹni ti o si tun dagba to bayi niru akoko ti a wa, ti a n lọwọ yi si tun wa.
Onirunru ọrọ ni awọn eeyan si n sọ ti niise lawọn ti wọn da iya agba naa mọ nigba aye rẹ tun sọ pe kokoko lara iya naa le saaju ọjọ iku rẹ.
Gẹgẹ bi Ikanni Sakilọmọwa Rescue Mission se gbe jade sori itakun ayelujara ikanni Facebook rẹ wọn ni iya agba naa nrin kosakosa laifi ọpa rin fọpa tẹlẹ pẹlu bi o ti lọjọ lori to.
Wọn se apė̵rẹ iya naa gẹgẹ bi akanda eeyan kan latari awọn iwa ati ise rẹ nigba aye rẹ
Iroyin iku iya agba ẹni ọdún Mẹ́rìndínlígba ọhun ni o gba ori ikanni ayelujara lọjọ isẹgun Tuesday ti ọpọ awọn eeyn si n s’adua pe k’Ọlọhun o tẹ iya agbalagba naa si afẹfẹ rere.
Njẹ a le ri ẹni ti oun pẹlu naa le dagba laitẹ, laiwọ tabi fọpa rin bi ti iya agba yii ni iru asiko ti a n lo yi.
Gẹgẹ bi ibeere ti awọn eeyan kan nbeere, bakan naa gẹgẹ bi awọn onimọ nipa ilera ti ma nsọ lọpọ igba nipe onirunru awọn aisan lo n wọpọ ti o n se awọn eeyan latara ohun ti wọn n jẹ ti wọn n mu ati ohun wọn n se.
Awọn ohun kan ti o n ge ẹmi eeyan kuru bakan naa wọpọ lara awọn ti wọn nle pa loojọ.
Ninu onirunru awọn alaye ọrọ awọn akọsẹmọse eleto ilera ti eeyan bale gbiyanju a ti tẹle o daju pe ọpọ ni yoo ma lo igba ati akoko rẹ ni alaafia ti wọn o si ni dalabọ ara tabi fọjọ ọlọjọ lọ.
Sugbọn aile tẹle awọn ila naa bi ka jẹun wa lasiko, ki a mu omi ni amuto, ki a gbiyanju a ti maa jẹ eso, ki asun oorun wa ni asiko ti o yẹ, ki a sinmi lẹyin isẹ, ki a si yee wa ohun ti o sọnu kiri.
Gbogbo awọn ilana se ati mase gbogbo wọnyi wa lara ohun ti o n muniyan gbaye pẹ ti eeyan bale tẹle.
Ni nkan bi ọdun diẹ sẹyin ni awọn ajọ kan gbe jade pe iku awọn ọdọ, awọn agba ti ko lọjọ lori ti n pọ lasiko yi kọja bi o ti yẹ ti abajade iwadi wọn si jẹki o di mimọ pe imukumu, ifakufa ko ida ti o pọ lara okunfa iku awọn ọdọ naa.
Nitori naa bi eeyan bafẹ pẹ laye o ni lati tẹle awọn ilana ti o rọmọ eto ilera rẹ ati awọn ilana ti awọn eleto ilera lakalẹ.