Iroyin pajawiri

Ọwọ tẹ àwon Afurasí ajìjàgbara Odua Nation mérìndínlógún pẹ̀lú ohun ìjà olóró lakoko ti won ya wọ ọgbà ọ́fìsì Gómìnà ipinlẹ Oyo

Niise l’awọn Eeyan kan ti won furasi pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Ajijagbara Oodua Nation yawọ inu Ọfisi Gomina nilu Ibadan tiise Olu-ilu ipinle Oyo l’owurọ ọjọ Abameta Satide, ojo ketala, osu kerin, odun 2024 ti a wa yi.

Awọn ajijagbara naa ni wọn tun yawọ ile igbimọ aṣofin Oyo, ti wọn si parọ asia orilẹede Naijiria pẹlu ti Odua Nation ki awọn ọmọ ologun to de si ibẹ.

Fọnran fidio kan lo safihan awọn eeyan naa ti wọn wọ aṣọ ologun lasiko ti won nawọ gan wọn- ti won ti fi gbooro-ofin gbe won bayi.

Bakan naa ni fọnran ọhun tun safihan bi ọwọ Ileeṣẹ Ọlọpaa ṣe tẹ wọn, ti wọn si da wọn dubulẹ ninu ọgba naa

Nigba to n fi iroyin naa mulẹ, oludamọran fun Gomina lori eto abo nipinlẹ Oyo, Fatia Owoseni Rtd ni ọwọ ti tẹ awon afurasi mẹrindinlogun lara awọn afurasi naa.

Bakanna, Oludamọran fun Gomina lori iroyin, Abosede Sodiq fidi isẹlẹ naa mulẹ, o ni bi wọn se yawọ inu ọgba ọfisi Gomina ni wọn si bẹrẹ si ni yin ibọn soke.

O ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ pupọ awọn afurasi naa wọn si wa lakata wọn

O ni, awon ti ke si awọn araalu ki wọn fura nitori awọn eeyan ọhun ni wọn mura ninu aṣọ ologun, nitori naa ti wo̱n ba ri iru awọn eeyan bẹ ki wọn o fura si wọn.”

Nibayii, ọpọ awọn ikọ eleto-aabo, lati olu Ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ologun ati awọn Amọtẹkun lo ti wa kaakiri agbegbe naa lati ri pe alaafia jọba.

Bakan naa ni wọn ti gbe igi dina awọn oju ọna ti wọn si rọ awọn araalu lati ma gba agbegbe ti wọn gbe igi di ọhun kọja lasiko yi.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ìmáàmù Agba Ogbomoso tu ba o, o rawọ-ẹbẹ sí Sọun tilẹ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlabi, pe ko má bínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ t’oun bá ṣẹ̀

Lẹyin ọpọ awuyewuye, gbonmisi-omi-o-t o ti waye fun igba pipẹ laarin Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *