Iroyin pajawiri

Ooru yóò tún mú jù bayi lọ l’Oriléèdè Naijiria, Àjọ to n ri si ojú ọjọ́ iyen Nimet lo sọ bẹ

Ooru tó n mú ní Orilẹede Nàìjíríà ṣì máa mú síi jù báyìí lọ, òsise àjọ Nimet kan lo ṣàlàyé ìdí ẹ ti o fi ma ri bẹ.

Arabinrin Olumide Olaniyan, to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ Nimet, iyẹn ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ oju-ọjọ ni Orileede Naijiria ti sọ wipe ooru tun maa mu sii ju bayii lọ, ‘’ti a ko ba ṣọra.’’

O ni ooru ti o n mu lẹnu ọjọ mẹta yii ni i ṣe pẹlu nnkan ti wọn n pe ni ‘’ENSO.’’

Arabinrin Olaniyan sọ pe ‘’awọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi ti wọn ri si oju-ọjọ ti sọ ṣaaju tẹlẹ pe ti ‘El-Nino’ ba ti wa, oju-ọjọ a maa gbona riri

Kii ṣe Orileede Naijiria nikan ni kini ọhun si bawi, gbogbo agbaye ni.

O ni, o kan jẹ pe ni apa ọdọ tiwa nilẹyi nnkan ti o ma ṣẹlẹ ni pe ojo ko ni pọ, atẹgun to n fẹ lọsan an ati loru yoo si maa gbona janjan.

Ti a ba n sọ pe ojo ko ni pọ ko tumọ si pe ojo ko ni rọ lawọn ibomiran ti yoo fa omiyale agbara ya ṣọọbu, amọ sibẹ ojo koni pọ to nkan.

Ojo yoo rọ lawọn ibikan ti yoo si fa omiyale nitori pe ‘El-Nino’ lo n ṣẹlẹ lọwọ, o ṣi maa n jẹ ki oriṣiiriṣii nnkan ṣẹlẹ kaakiri agbaye.

Ni awọn ilu miran, ojo ti o maa gbe gbogbo nnkan lọ lo maa rọ nibẹ, ṣugbọn lọdọ tiwa ni Naijiria nibi, ojo o ni pọ bo ṣe maa n pọ to tẹlẹ lọdọọdun.

Ohun lo jẹ ka maa ri pe ojo o ti bẹrẹ si ni fẹsẹ mulẹ kaakiri, gbogbo ibi to yẹ ko ti fẹsẹ mulẹ ninu ọdun yii.

Asọtẹlẹ awọn onimọ nipa oju-ọjọ sọ pe ooru to n mu yii, yoo mu lati oṣu Kinni titi di oṣu Karun-un.

Yoo si fẹ to osu kẹfa ki ojo o to fidi mulẹ daadaa, o ni ooru to dinku diẹ, kii ṣe pe yoo dinku bi ti ọdun to kọja pẹlu bi o ti wulẹ ki ojo naa rọ to, ooru yoo ṣi maa mu, ṣugbọn ko wa ni dabi bo ṣe ri lọwọ bayi.

O ni ooru amuju ọhun naa yoo ṣakoba fawọn irufẹ ẹranko kan to jẹ pe a le ma ri iran awọn ẹranko bẹ mọ tori bi oju-ọjọ se ri.

Arabinrin Olaniyan salaye pe ”ti omi okun Pacific ba ti n gbona ju bo ti yẹ lọ, atẹgun gbigbona lo maa maa fẹ kaakiri agbaye.

Bakan naa lo si jẹ pe Ooru yii tun maa lagbara si, ti a ba ti n sun awọn nkan bi igi, sun ewe atawọn nnkan mii wọnyi lawọn nkan to jẹ ki oju-ọjọ maa gbona niyii.

Ooru yoo tun mu ju bayi lo o – Ajọ to n risi oju ọjọ iyen Nimet lo salaaye oro bẹ.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Iléẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti fòntẹ̀ lù ìdájọ́ ikú oloye Ramon Adedoyin latari po lọwọ nínú ikú tó pa Akẹkọọ OAU Timothy Adegoke.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti o fi di kalẹ niluu Akurẹ ti buwọ́lù idajọ iku fun …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *