Iroyin pajawiri

Zack Orji o ku o, E yé gbé ìròyìn eléjè kiri – Ààre ẹgbẹ́ àwọn òsèré kùnrin elédè òyìnbó, ìyen Actors Guild of Naijiria AGN, Emeka Rollas lo pariwo síta bẹ.

Lẹnu nkan bi ọjọ mẹta yii ni awuyewuye gba ori itakun-ayelukara kan, pe gbajumọ osere-tiata ọmọ Igbo nni, Zack Orji, ti dagbere f’aye.

Eyi ri bẹẹ latari iṣẹ abẹ kan ti wọn kede pe ọkunrin naa nilo lati ṣe ni kiakia, nitori ara rẹ ti ko le lẹnu lọọlọ yii.

Nigba to n tan imọlẹ si ọrọ naa, Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Actors Guild of Nigeria (AGN), Emeka Rollas, sọ pe irọ bansa ni pe Zack Orji ti ku, Zack orji o ku, o si wa laye.

Aarẹ ẹgbẹ naa sọ pe ofege ni iroyin to kede iku gbajumọ oṣere ọmọ Igbo naa.

O ni ‘’Ẹ waa tẹti gbọ awa ti a ko ni i purọ fun yin, Zack Orji ṣi wa laye, laaye.

Rollas so wipe, ‘’Awon mọ pe ero awọn kan niyẹn, ṣugbọn Zack yoo ye, ko ni ku, yoo si pada sẹnu iṣẹ ere sise’’

Mínísítà fọ́rọ̀ Aṣa nilẹwa Naijiria ti wa n bèèrè ìrànwọ́ owó fún Zack Orji, kí ìtọ́jú rẹ̀ le yá kíákíá.

O ni, Arẹwa ọkunrin to duro deede to si mọ iṣẹ rẹ niṣẹ ni Zack Orji ko too di pe aisan bẹrẹ si ba finra.

Lọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an ọdun 2023 yi ni oṣere tiata naa to maa n ṣere oloyinbo di ẹni ti wọn gbe digba-digba lọ sogba ile-iwosan kan to wa l’Olu-ilu ilewa l’Abuja.

Hannatu Musawa, ẹni ti i se Minista fun Aṣa ni Naijiria, beere iranlọwọ awọn eeyan fun Orji ki itọju rẹ le ya kiakia.

O ti pẹ to ti n gba itọju nileewosan, ko too di pe iroyin naa jade laipẹ yii pe o ti jade laye.

Emeka Rollas koro oju sawọn ẹka iroyin to n gbe iku Zack Orji lai ti i ku, o ni kẹnikẹni ma ṣe gba wọn gbọ rara.

Oserekunrin naa ni oun ki i gbe igbesi aye oun sori itakun-ayelukara.

Zack Orji sọ pe oju opo agbaye ki i ṣe ibi toun maa n sọ bo ṣe n lọ laye oun si.

Ọmọ Igbo ni Zack Orji, ṣugbọn orilẹ-ede Gabon ni wọn bi i si.

Ọmọ bibi Ngwoo, nijọba ibilẹ Udi, nipinlẹ Enugu ni.

Ileewe giga fasiti Naijiria, ti o wa ni Nsukka lo ti kawe gboye.

Zack Orji ti figba kan ṣiṣẹ niluu oyinbo, South Africa atawọn orilẹ-ede mi-in ko too dara pọ mọ ẹgbẹ oṣere ni Orileede Naijiria.

Osere tiata nni Zack le sọ ede Igbo, Faranse ati ede oyinbo daadaa.
Ki Elédùà ba wa d’áwọ le. ki o ma fi iku ti o yawọ pa ẹnikọọkan wa

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ó màse o, Oriyomi b'omijé lójú lásìkò tó n ba àwọn olólùfẹ́ rẹ sọrọ lẹ́yìn to jade kuro lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Ó màse o, Oriyomi b’omijé lójú lásìkò tó n ba àwọn olólùfẹ́ rẹ sọrọ lẹ́yìn to jade kuro lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

  Gbajugbaja agbohunsafẹfẹ nni, Oriyọmi Hamzat, ti bawọn ololufẹ rẹ sọrọ lati mọ riri wọn …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *