April Fool kọ o, ẹ maa fagbo lọ, ijọba Orileede Germany lo jan lonte bẹ.
Awọn eeyan orileede Germany kan wa to jẹ pe wọn kundun lati maa fagbo lẹyin ti wọn ba pari iṣẹ oojọ wọn, ọti sini awọn mi nifẹ si lati mimu.
Gbolohun naa lo jade lẹnu Marcel Ritschel to n dawọ idunnu lẹyin ti ijọba orileede Germany fun awọn eeyan ti wọn fẹ ọti mimu ti awọn mi si faramọ igbo fifa ni iyọnda lati maa fagbo lọ.
Bẹrẹ lati ọjọ Kini oṣu Kẹrin, ni ijọba orileede naa ti faaye gba igbo fifa fun araalu amọ igbalaaye, igbesẹ naa wa labe ilana-ofin ilu naa.
Awọn agbofinro orileede naa lo ti wa n ke gbajare bayi pe ewu nla n bẹ loko longẹ pẹlu igbesẹ naa ti ijọba ilẹ wọn gbe.
Ofin ọhun ti jọba kede rẹ ni wọn ni yoo gberasọ, bẹrẹ layajọ April Fool.
Niiṣe lawọn eeyan ti bẹrẹ sini fa igbo ni ita gbangba ṣaaju ki ijọba to kede didẹkun ofin to de fifagbo to wa nilẹ naa tẹlẹ.
Lara awijare to mu ki wọn faaye gba igbo fifa naa nipe aimọye lo ti n fa igbo tẹlẹ ki ijọba to ni awọn faaye gba.
Wọn tun sọ pe yoo dẹkun awọn to n ta igbo lọna ẹburu nigba ti igbalaye ba ti wa lati ta nita gbangba.
Ohun t’awọn to n ja fun fifa igbo ni ita gbangba sọ ree gẹgẹ bi awijare ti wọn.
Wọn ni kii se gbogbo eeyan bikose awọn ti ọjọ ori wọn ba kọja ọdun mẹrindinlogun ni wọn le mu igbo ti iwọn rẹ jẹ 25kg nita gbangba ti ko si ni tako ofin.
Awọn agbalagba le gbin igi igbo mẹta ni idile kọokan
Ṣugbọn awọn eeyan ko ni lanfaani lati fa igbo layika ile ẹkọ, ibudo idaraya tabi ibi tawọn to n fẹsẹ rin loju popo ba wa laarin ago meje owurọ si ago mẹjọ alẹ.
Aaye wa fun idasilẹ ẹgbẹ onifaaji awọn to n gbin igbo, ti ọmọ ẹgbẹ ko si gbọdọ ju ẹẹdẹgbẹta lọ.
Ọjọ ori awọn ọmọ ẹgbẹ gbọdọ kọja ọdun mejidinlogun, ti wọn si gbọdọ jẹ olugbe ilu Germany.
Awọn ẹgbẹ naa gbọdọ lanfaani lati gbin, ki wọn si ṣalabapin igbo ọhun ṣugbọn wọn ko gbọdọ ṣe bẹẹ lọna ati fi pa owo.
Ko saaye fun wọn lati fa igbo yii ni aaye ti wọn ti n gbin igbo.
Ni bayi ti Orileede Germany ti wa faye gba won eeyan orileede wọn lati ma fa igbo, Ọ́pọ̀ ọdọ ti ọjọ ori won ko tii to ọdun mejidinlogun ni yoo maa wa ọna alumokoroyi lati ra igbo naa.
Ọjọ ti pẹ ti awọn to n mu igbo ti fẹ ki wọn ṣọ mimu ati tita rẹ di ohun ti ofin faaye gba.
Bawọn kan ṣe n yayọ ofin tuntun ọhun ni awọn kan tako.
Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Ray Walley ṣe sọ o ni ilana tuntun ọhun ni yoo ṣe akoba fun ilera, ti yoo si tun mu alekun ba iye awọn to n fa igbo.
O ni pẹlu pe awọn ti ọjọ ori won ko ti to ọdun mejidinlogun ko le jẹ anfaani ofin naa amọ pupọ awọn ọdọ ni yoo maa wa ọna alumokoroyi lati ra igbo.
Lọwọ bayi Orileede Germany wa lara awọn orileede to ti n ṣe iye meji lori ọrọ fifi ofin de igbo fifa nita gbangba.
Ni orileede Canada, o ti ṣe diẹ ti igbo mimu ati tita lai bẹru agbofinro ti di gbẹfẹ ati ni awon orileede mi bakan naa.