Iroyin pajawiri

Tinubu sèpàdépọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ Afẹ́nifére, o sèlérí pe k’áwọn aráàlú se sùúrù, oun o tun Oríléèdè Nàíjíríà se

Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu tun ti ṣe ileri ọtun fun ẹgbẹ ọmọ Yoruba iyẹn ẹgbẹ Afẹnifẹre lati se suuru o ni oun o tun orileede Naijiria ṣe, ti gbogbo nkan yoo si ipadabọsipo.

O ni ko dajupe kosi ojusaaju ni gbogbo ẹka, amọ oun ti fi ara oun jin lati lewaju Naijiria lọ sibi aṣeyọri eto ọrọ aje ati igbe aye to ṣee fi yangan eyi ti o jẹ oun logun kọja ohunkohun.

Aarẹ Tinubu wa ṣe ileri yii lasiko abẹwo to ṣe lọ sọdọ awọn olori ẹgbẹ naa ni ile Alagba Reuben Fasoranti to wa niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo l’Ọjọru, Wednesday, ọsẹ yii.

Nibẹ lo ti ṣeleri pe Orileede Naijiria yoo la asiko ipenija eto ọrọ aje ti o dẹnukolẹ yii koja, nitori pe lẹyin ohun gbogbo, ayọ ni yoo pada ja si.

O ni orileede Naijiria yoo la ipenija eto ọrọ aje to wa ninu ẹ lasiko yii ja, Imọlẹ yoo tan lẹyin gbogbo rogbodiyan yii.

Aarẹ ni oun gba gbogbo ohun to n ṣẹlẹ lasiko yii mọra.

O ni gbogbo ohun to yẹ ki awọn o ṣe ni awọn n ṣe lati tẹle ilana eto agbaye, o ni awon ko tii ṣe kọja aaye, awon ko si nii kọja aaye awon.

O ni Gbogbo ọna ti awon mọ lawon n tọ lati rii pe Naijiria de ibi aṣeyọri rẹ.

Aarẹ ni sọ pe Ipenija eto ọrọ aje ti a n la kọja latigba ti oun ti gba ijọba ko jẹ tuntun si oun.

Gẹgẹ bi gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, O ni oun koju awọn iṣoro to jọ eyi, ti awọn eeyan si pe ipe lati kọwe fipo silẹ.

“Ṣugbọn nipasẹ ọkan akikanju ati igbesẹ to yẹ, ipinlẹ Eko gun oke agba si ipo karun ti eto ọrọ aje wọn n ṣe daadaa nilẹ Afrika.

O ni “Awon ni lati rọra lo awọn ohun ti awon ni pẹlu ọgbon ati imọ lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje ilẹwa Naijiria.

Aarẹ ni, oun gbe apoti, oun si ṣe ipolongo lati sin Naijiria nipa ifẹ Naijiria, awọn araalu si se bẹ dibo fun oun.

Niise ni awọn kan sọ pe oun o le pẹ nipo, latari ẹjo Tribuna, ti wọn si bẹrẹ sii sọ oriṣiriṣi, o ni gbogbo bi awon se wa nile ẹjọ, oun si tun ni afojusun lati kọju si ibi ti oun lọ laisiye meji.

Oni, oun ni ipinnu lọkan ara oun lati ṣatunṣe eto iṣuna, ati lati fopin si iwa imọ-ti-ara-ẹni nikan laarin awọn ẹka ijọba.

Akọwe agba ijọba orileede yii nigba kan ri, Alagba Olu Falae nigba to n gba ẹnu Alagba ẹgbẹ Afẹnifẹre, Fasoranti sọrọ, o gbe oriyin fun Aarẹ Tinubu lori akitiyan rẹ si itẹsiwaju Orileede Naijiria, bẹẹ lo ṣeleri lati ṣatilẹyin fun isejọba rẹ.

O ni, Wọn mọ awon fun iwa ọmọluabi, ẹni to koju oṣuwọn, otitọ ati akinkanju.

Àbájáde ìpàdé Ààrẹ Tinubu àti àwọn olórí ẹgbẹ́ Afenifere naa lo da lori ípa ìnira tí aráàlú ń kojú lori ọwọn gogo.

Ààrẹ Bola Tinubu lo ṣe àbẹwò sì adari ẹgbẹ Afenifere naa iyẹn Pa Reuben Fasoranti fún igbà akọkọ lẹyìn ti o di ààrẹ orilẹede Naijiria.

Nipasẹ abẹwo naa ni ipade alatilekunmorise fi waye pelu adari ẹgbẹ Afenifere ati awọn agba-gba ẹgbẹ bi Bashorun Sehinde Arogbofa, Akọwe ìjọba àpapọ̀ tẹlẹ Ọba Olú Falae.

Agbẹnusọ fún ẹgbẹ Afenifere Ogbeni Jare Àjàyí sọ pẹ awọn ẹgbẹ Afenifere ba ààrẹ Tinubu sọrọ lórí atunto orileede Naijiria ni ẹka òṣèlú, ọrọ ajé, ìbarà ẹni gbepọ ati awọn ẹka miran.

Lara awọn nnkan ti ẹgbẹ Afenifere lawọn bere fún nipa atunto orileede Naijiria ni ki awọn agbegbe le lẹtọ sì ànfàní lori awọn ohun alumọni ti ìjọba ba ri l’agbegbe wọn

Gẹgẹ bi o ṣe wa bayi, awọn agbegbe ti orileede Naijiria ti n ri epo rọbi lo ni ànfàní sì awọn owo kan sùgbọ́n eleyi ko gbọdọ̀ wa fún epo rọbi nikan, awọn àgbègbè ti ohun alumọni ilẹ̀ wa naa lẹtọ lati maa gba awọn owo kan naa lọwọ ìjọba gege bi ẹtọ wọn.”

Ogbeni Jare Àjàyí ninu ijabọ rẹ sọ pe ààrẹ Tinubu fi daa Pa Fasoranti ati awọn agba Afenifere loju pe ìnira ti awọn ọmọ Nàìjíríà n koju lọwọ yii yóò di ohun afiseyin teegun n fiṣo.

O ni “Ààrẹ sọ fun awon pe, ṣe ni oun gbàdúrà lati di ààrẹ orilẹede Naijiria, o ni Gbogbo idojukọ ibẹ naa si ni oun ti gbaradi fún.

Aarẹ sọ pe gẹgẹ bi oun ṣe ṣe ni ilu Eko ti o fi di ipinlẹ ti ọrọ ajé rẹ ni idagbasoke julọ ni ilẹ Africa bẹẹni oun fé fi ipilẹ to muna doko kalẹ fún atunto Naijiria.

Àjàyí sọ pẹ ààrẹ Tinubu gbe iwe moyege ti Ajọ eleto-idibo INEC fún oun hàn adari ẹgbẹ Afenifere.

Gomina ipinlẹ Ondo Lucky Aiyedatiwa ati Gomina ana dokita Olusegun Mimiko wa lara awọn to peju pesẹ sibi ìpàdé naa ti wọn si kọwọrin pẹlu Aarẹ Bọla Tinubu.

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Ààrẹ Tinubu ti já awọn Ọmọ Naijiria kulẹ̀, kòsí ìyàtọ̀ làárín isejọba rẹ̀ àti Adolf Hitler

Aarẹ Ona Kakanfo tilẹ Yoruba, Iba Gani Adams sọ pe Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *