Iroyin naa lo bani lọkan jẹ ti o si ko awọn eeyan agbegbe Temidire lọna ti o lọ silu Ajaawa lọkan soke latari bi idike ẹlẹni mẹfa naa se dero ile iwosan lẹyin ti wọn jẹ Amala tan.
Gẹgẹ bi iroyin naa ti a gbọ iya agba kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Abilekọ Victoria Paul Adewọle pẹlu awọn ọmọ rẹ mẹrin ati ọmọ ọmọ rẹ ọmọde binrin kan ni wọn jọ jẹ amala naa lalẹ ọjọ’ru Wednesday gẹgẹ bi ounjẹ alẹ wọn.
Lẹyin ounjẹ alẹ naa ni iya awọn ọmọ ọhun pẹlu irora nahun pe awọn alaba gbe wọn, ti wọn si gbe gbogbo wọn lọ sile iwosan aladani kan lagbegbe ileewe Girama onitẹbọ iyẹn Baptist High School nibẹ ni wọn si ti jẹki o di mi mọ fun wọn pe ọmọde binrin tii se ọmọ ọmọ arabinrin naa ti dakẹ ni ti ẹ.
Awọn yoku arabinrin naa ati awọn ọmọ rẹ mẹrin ni wọn ni ki wọn o ma gbe lọ si ile iwosan Bowen, amọ ohun ti a gbọ tun ni pe niise ni Bowen kọ lati gba wọn ti wọn si dari wọn lọ si ile ẹkọsẹ imọ isegun oyinbo ati itọnu Lautech iyẹn Lautech Teaching Hospital nibẹ ni wọn si ti n gba itọju nipa didu ẹmi wọn.
Alajọ gbele wọn kan ti o ba awọn oniroyin sọrọ ẹni ti ko fẹ ki wọn mọ orukọ sọ pe o jọ bi ẹni pe wọn da wọn Elubọ ẹgẹ pọ mọ ti isu leyi ti o si le sakoba fun inu.