Awọn ẹlẹsin Isẹse lagbaye, International Council for IFA Religion ti wọ ajọ ọlọpaa Naijiria ati Emir ilu Ilorin lọ ile ẹjọ giga ti o wa nilu Ilọrin ti ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn agbẹjọro onisẹse ẹlẹsin abalaye naa, Lọya Femisi, ṣe sọ o ni ipinnu awọn onibara oun lati wọ ajọ Ọlọpaa lọ ile ẹjọ ko sẹyin bi wọn ṣe da awọn onisẹse Ilu Ilọrin duro lati se ọdun Isẹse wọn ti agbaye to yẹ ki o waye ni ogunjọ oṣu kẹjọ, ọdun 2023 ọdun ti o kọja.
Ti a o ba gbagbe latara rogbodiyan awọ ti o ti ipa iya onisẹse kan ran mọ ti gbajumọ onisẹse lori afẹfẹ Ọgbẹni Abdulaziz ti ọpọ eeyan mọ si Tani Ọlọhun ni ọrọ naa ti n rugbo bọ
Ọdun isẹse ni arabinrin naa fẹ se nigba naa ti aworan iwe ipe ti o se fi gba ori itakun ayelujara pa ti awọn eeyan si bẹrẹ si yọnusọ si iwe ipe naa pe ọdun isẹse ni ilu ẹsin Islam.
Eyi lo mu ki awọn alfa ilu ilọrin bẹrẹ si fi ohun ransẹ si iya onisẹse naa pe ti o ba to bẹ ki o se ọdun rẹ nilu ilọrin latari idunkoko naa ni ileesẹ ọlọpaa fi pada da iya onisẹse naa lọwọ kọ lati mu ki alaafia o jọba lasiko naa.
Agbẹjọro awọn ̇onisẹse Ọgbẹni Fẹmisi salaye pe ajọ ọlọpaa sọ pe ki awọn oniṣẹṣe gbe ọdun wọn kuro ni ilu Ilọrin leyi ti o jẹ pe ko ba ofin mu.
O ni ọrọ naa lo dabi ẹni n fi ẹtọ wọn dun wọn lati ni ki wọn o gbe ọdun wọn kuro nilu ti wọn n gbe.
Eyi ni koko ohun ti o faa ti awọn ẹgbẹ onisẹse lagbaye fi gbe ẹjọ naa dide si ajọ ọlọpaa ati Emir Ilu Ilọrin ati awọn tọrọ kan lori irufẹ igbesẹ bẹ.
Agbẹjọro fun awọn onisẹse naa Ọgbẹni Femisi sọ wi pe awọn ọrọ ti ọga agba ọlọpaa sọ lori afẹfẹ lọjọ ọdun naa yatọ gedegbe si ọrọ ajọsọ awọn nigba ti awọn se ipade pọ pẹlu wọn.
O fi kun un pe awọn ni ẹri to daju lati gbe kalẹ fun ile ẹjọ.
Igbẹjọ naa to waye lo bẹrẹ loni ọjọ kẹrindinlọgbọn niwaju Adajọ Taoheed Umar.
Agbẹjọro agba, Oloye Malcolm Omirhobo (SAN) lo duro fun awọn onisẹse nile ẹjọ.
Tẹ o ba gbagbe, Ọgbẹni yi ni ogbontarigi agbẹjọro ajafẹtọ ọmọniyan toun pẹlu naa si jẹ ẹlẹsin isẹse.
Oun kan naa lo mura bii Babalawo wọ ile ẹjọ ‘Supreme’ l’Abuja ati ile ẹjọ giga ijọba apapọ niluu Eko losu kẹfa ọdun 2022.