Tilu tifọn pẹlu omije ati ariwo ẹkun ni awọn araalu fi pade oku Gomina ana Rotimi Akeredolu niluu Owo.
Niise ni won gbegidina ọpọ agbegbe- to wa ni ilu naa nitori ọpọ eeyan fẹ ri oku rẹ bi wọn se gbe wọlu.
Agbegebe Emure niluu Owo kun fun ero bi ilu ṣe tẹwọgba oku Gomina Rotimi Akeredolu pẹlu iyi ati ẹyẹ.
Ariwo Aketi Aketi ni ọpọ awọn eeyan araalu mu bọ ẹnu.
Ọkọ agboku lo gbe oku naa to si gbe kaakiri ilu, ti awọn akẹkọọ pẹlu ọgọrọ eeyan si n juwọ pe odigba o se.
Ara, ọrẹ, ojulumọ ati awọn alabaṣepọ lo korajọ lati ṣẹyẹ ikẹyin fun un ologbe naa l’ọjọ Ẹti Friday, ọjọ ketalelogun, oṣu Keji, ọdun 2024.
Ile ijọsin St. Andrew Cathedral to wa nilu Ọwọ to jẹ ilu abinibi rẹ ni eto isinku naa ti waye.
Ọpọ awọn eeyan to wa nibẹ ni wọn kọminu, ti wọn banujẹ lori ipapoda ẹn nla naa Gomina Akeredolu, ẹni to ti ṣiṣẹ takuntakun ninu idagbasoke ipinlẹ naa, paapaa lẹka eto aabo.
Igbakeji aarẹ Orileede Naijiria, Kashim Shettima, lo ko awọn gomina gomina sodi lati wo bi akẹgbẹ wọn tẹlẹri naa ṣe fẹẹ wọ ka-ilẹ sun.
Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa lo gbalejo gbogbo awọn gomina ọhun.
Lara awọn gomina naa to peju jo sibi eto-isinku naa ni Gomina Ipinle Oyo, Onimo-ero Ṣeyi Makinde; Gomina Godwin Obaseki ti ipinlẹ Ẹdo; Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko.
Alaga ẹgbẹ oṣelu Oloosusuowo APC ni Naijiria, Abdullahi Ganduje, Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ogun ati Ondo, Kayọde Fayẹmi; Sẹnetọ Gbenga Daniel ati Olusegun Mimiko naa ko gbẹyin nibẹ.
Bakan naa ni Gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetola ati awọn miran pẹlu naa wa nibẹ.
A o ranti pe, Akeredolu ni alaga ana fun ẹgbẹ awọn gomina gomina lẹkun Iwọ-Oorun Naijiria nigba aye rẹ.
Oun naa si ni igi lẹyin ọgba fun idasilẹ ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun lati gbogun ti eto-aabo to mẹhẹ ati awọn agbebọn ajinigbe to n sekọlu s’awọn Araalu.
Aṣọ ikọ eleto abo Amọtẹkun ọhun ni wọn gbe sori poosi rẹ, lati fi yẹ Oloogbe naa Akeredolu si.
O jade laye niluu Germany, ti wọn si gbe oku pada si orilẹede Naijiria ni ọjọ karun un oṣu kini ọdun 2024.
Laravawọn ẹbi ologbe to wa ni bi isin idagbere naa ni Iyawo oloogbe fun ra rẹ Betty Anyanwu Akeredolu, Adajọ Bolaji Olajuwon, Oluwarotimi Odunayo Akeredolu Jnr, Babajide Akeredolu, Lady Ifeoma Atuegwu, Dr Teniola Akeredolu Micheals ati Pastor Kola Akeredolu.
Akeredolu jade laye lẹyin aarẹ to ti ba finra fun igba diẹ.
Ohun ni Gomina ipinlẹ iwọ oorun Naijiria keji ti yoo ku lori oye.
Ninu itan oloṣelu Naijiria awọn eeyan ko ni gbagbe Rotimi Akeredolu to jẹ akọṣẹmọṣẹ agbẹjọro agba to si tun jẹ gbajugbaja oloṣelu ni Naijiria.
Ọdun 1956 ni wọn bi Oluwarotimi Odunayo Akeredolu to si jẹ ọmọ ilu Owo ni ipinlẹ Ondo.
Arakunrin ni inagijẹ rẹ ti ọpọ a maa pe paapa lagbo oṣelu ipinlẹ Ondo nibi to ti jẹ Gomina fun saa meeji ọtọọtọ.
Ile ẹkọ ibẹrẹ Government School lo ti bẹrẹ ẹkọ rẹ to si tẹsiwaju lati ibẹ lọ si St Aquinas College, Loyola College ni Ibadan ati Comprehensive High School Aiyetoro nibi to ti gba satifiketi ile ẹkọ girama.
Ile-eko giga Fasiti Obafemi Awolowo nilu Ile Ife lo ti kẹkọ nipa imọ ofin to sipari ẹkọ rẹ lọdun 1977.
Ọdun 1978 ni wọn pe si ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorileede Naijiria.
Gẹgẹ bii ọpọ araalu ṣe sọ, ẹlẹyinju aanu ni Arakunrin Rotimi Akeredolu nigba aye rẹ.
Awọn araalu sọ ninu ọrọ wọn pe pẹlu bi o ṣe jẹ pe Akeredolu ti jade laye, yoo si wa ninu akọlẹ pe o jẹ olori to ni afojusun rere fun ilu.
k’Ọlọrun ọba o dakun se iku ni isinmi fun.