Iroyin pajawiri

Ó dójú ẹ o, Àjọ EFCC kéde ìyàwó Emefiele ati àwọn mẹ́ta mìíràn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá

Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu-isowo ilu basubasu nílewa Nàìjíríà, Ajọ EFCC ti kéde ìyàwó gómìnà àná fún banki Apapọ ilewa CBN l’Orileede Nàìjíríà, Godwin Emefiele, Margaret Dumbiri Emefiele ni wọn ti kede rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá.

Margaret Emefiele àti àwọn mẹ́ta mìíràn, òṣìṣẹ́ banki Apapọ CBN kan, Eric Odoh, obìnrin oníṣòwò kan, Anita Omoile àti òṣìṣẹ́ Bureau de Change kan, Jonathan Omoile ni Ajọ EFCC fi orukọ wọn sórí itakun Ayelukara X pé awọ́n ń wá wọn.

Nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi kéde àwọn ènìyàn náà bi ẹni tí wọ́n ń wá ni wọ́n ti sọ pé àwọn ènìyàn ọ̀hún lẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú gómìnà banki Apapọ ilewa CBN àná, Godwin Emefiele láti fi kó ọ̀bítíbitì owó tó wà fún ará ìlú sápò ara wọn, iwa ika-iwa ajebanu, iwa bamubamu ni moyo- won o mo b’epi n pa omo-eni kan naa ti wọn hu lo jẹ eyi ti o pada han sita.

Asiri-gbogbo awọn asebi-eeyan ti won n fi aye niwa lara l’Orileede Najiria yoo ma tu ni, kọọkan ni.

EFCC ní láti ìgbà tí àwọn ti nawọ́ gán Godwin Emefiele tí àwọn sì ti gbe lọ sílé ẹjọ́ ni ìyàwó rẹ̀ Magraret ti na papa-bora, niise ni Margareti salọ, tò sí lọ farasin láti ìgbà náà.

Koda, aworan awon eeyan mereerin ọhun ni Ajọ EFCC fi s’oju opo itakun Ayelukara X won.

Wọ́n ní ẹnikẹ́ni tó bá mọ bí ọwọ́ ṣe lè tẹ àwọn ènìyàn náà kò kán sí àjọ EFCC tàbí àgọ́ ọlọ́pàá tó bá sún mọ́ wọn.

Ìkéde naa lo tún jẹ́ ọ̀tun sí ẹ̀sùn tí gómìnà àná CBN, Godwin Emefiele ń kojú láti ìgbà tí ààrẹ Bola Tinubu ti ní kó lọ rọ́kún nílé ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹfà ọdún 2023.


 

Nipa admin

Ṣayẹwo Tun

Àkójọpọ̀ Ìròyìn ohun tí o sẹlẹ̀ jakejado Naijiria níbi ìwọ́de ìfẹ́honuhan ebi npa wa.

Kaakiri awọn ilu, ipinle yika orileede Naijiria lonii, ọjọ kinni oṣu kẹjọ ọdun 2024, o …

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *