Ẹka awọn to n ṣowo paṣiparọ owo t’awon eeyan mọ si Bureau de Change nilẹwa Naijiria awọn onisowo naa to wa nilu Abuja, olu ilu ilẹwa l’Orileede Naijiria ti kede pe awọn yoo dawọ iṣẹ duro.
Idi ti wọn lawọn fẹ tori rẹ ṣe bẹẹ ni nitori ọwọngogo dọla to tun se bẹ gbenusoke.
Ninu fọnran fidio kan ti ifọrọwanilẹnuwo to waye ni alaga ẹgbẹ naa ti ba ikọ iroyin BBC Hausa sọrọ, ọgbẹni Abdulahi Dauran sọ pe bẹrẹ lati ọjọ Kini oṣu Keji ọdun 2024 ni awọn yoo ti dase duro.
O ṣalaye pe ọwọngogo owo dọla yi se idiwọ, ko jẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ oniṣowo paṣiparọ owo naa ri iṣẹ wọn ṣe bo ti ṣe yẹ.
Ninu alaye rẹ, o ni ọwọngogo naa ni ko ṣẹyin b’awọn kan ṣe n ṣe idokoowo lori itakun-ayelukara ati bi idokowo crypto ti ṣe gbode lagbo okoowo sise.
O ni awọn iṣẹlẹ wọnyi lo mu ki iye dọla ta wọn foju ri kere si ju ti tẹlẹ lọ to si n ṣakoba fun awọn to n ṣowo rẹ loju aye.
Laipẹ yi ni banki apapọ Naijiria gbe awọn igbesẹ kọọkan lati fi fagbara fun Naira loju agbami ti dọla ti n tẹ ẹ ri.
Lara rẹ ni ṣiṣi aaye silẹ ki onikaluku maa ta dọla ni iye to ba ba de ọdọ wọn loju opo kan ṣoṣo ti ọlọja ati alabara yoo ti maa ta dọla ni iye ti ọja ba tọka si.
Eyi wa lara ipinnu aarẹ Bola Tinubu ninu ọrọ to ba araalu sọ lasiko ti wọn bura wọle sipo fun.
Ni igba taa n wi ọun, iye owo paṣiparọ dọla si Naira ni oju oṣunwọn ti ijọba wa ni ₦460 si dọla kan.
Loju opo tawọn egbe paṣiparọ bureau d change, iye Naira si dọla si jẹ ₦750.
Nilẹ toni to mọ yi, ọrọ naa ti buru jai ju tatẹyinwalọ ti awọn kan si n ta Naira ni ₦1,460 ni paṣiparọ owo dọla kan.