Iroyin pajawiri

Monthly Archives: February 2024

Ọ̀rọ̀ tún n bọ́rọ̀ bọ o, ẹgbẹ́ awọn oníṣèṣe lagbaye gbé Emir ilu Ilorin àti ọlọ́pàá lọ ilé-ẹjọ́ lórí bí wọ́n ṣe dá àjọ̀dún wọn dúró

Awọn ẹlẹsin Isẹse lagbaye, International Council for IFA Religion ti wọ ajọ ọlọpaa Naijiria ati Emir ilu Ilorin lọ ile ẹjọ giga ti o wa nilu Ilọrin ti ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara. Gẹgẹ bi ọkan lara awọn agbẹjọro onisẹse ẹlẹsin abalaye naa, Lọya Femisi, ṣe sọ o ni ipinnu …

Ka si »

Àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ondo, àwọn gominà gominà pẹ̀lu àwọn èekàn olósèlú ati èekàn láwùjọ ni wọ́n péjọ sẹ̀yẹ ìkẹhìn fún Akeredolu.

Tilu tifọn pẹlu omije ati ariwo ẹkun ni awọn araalu fi pade oku Gomina ana Rotimi Akeredolu niluu Owo. Niise ni won gbegidina ọpọ agbegbe- to wa ni ilu naa nitori ọpọ eeyan fẹ ri oku rẹ bi wọn se gbe wọlu. Agbegebe Emure niluu Owo kun fun ero bi …

Ka si »

O ma se o, Kìnìún fa òṣìṣẹ́ ileewe giga fáṣítì OAU ya perepere lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn-án tó ti ń fún-un loúnjẹ jẹ

Ọjọ buruku esu gbomi mu lọ naa jẹ fun akekoo ati awon oluko ̣l’ọgba Ile iwe giga Obafemi Awolowo fasiti Ile Ifẹ pẹlu bi Kinniun ọlọdun mẹsan kan se kọlu ẹni to n tọju rẹ to si gbemi lenu re. Gege bi iroyin naa se se lalaye, oloogbe Ọlawuyi Ọlabọde …

Ka si »

Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lo jí Ọ̀kànlélọ́gọrin le mẹ́fà, N81.6 Miliọnu ọgá rẹ̀ gbe salọ.

Ọwọ ṣikun awọn agbofinro ọlọpaa ti tẹ obinrin ọmọ ọdọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Blessing Effiong fẹsun kan pe o ji ẹgbẹrun mọkanlelaadọta dọla owo ọga rẹ gbe salọ. Gẹgẹ bi iroyin naa se fi idi rẹ mulẹ iṣiro owo naa ni Naira lo sunmọ mọkanlelgọrin N81.6 …

Ka si »

Pásítò àti Ìmáàmù ní panupọ̀ sọ pe àsìkò tó o, kí ìjọba àpapọ̀ wá ojútu sí s’oro ọ̀wọ́ngógó l’Orileede Najiria ki n kan o to yíwọ́ tan pata

Niise l’Àwọn ojise Ọlọrun, awon imaamu ke pajare sita si Ijọba àpapọ ilẹwa Nàìjíríà lori isoro-ipenija owongogo ounjẹ to n dojuko awon Araalu. L’Ọjọbọ tọside ọsẹ yii ni agbarijọpọ ẹgbẹ awọn omo-lehin-Kristi ati ti Musulumi lorileede Naijiria fohun sọkan rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ lati wa ojutu, ọna abayọ si …

Ka si »

Ó dójú ẹ o, Àjọ EFCC kéde ìyàwó Emefiele ati àwọn mẹ́ta mìíràn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá

Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu-isowo ilu basubasu nílewa Nàìjíríà, Ajọ EFCC ti kéde ìyàwó gómìnà àná fún banki Apapọ ilewa CBN l’Orileede Nàìjíríà, Godwin Emefiele, Margaret Dumbiri Emefiele ni wọn ti kede rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá. Margaret Emefiele àti àwọn mẹ́ta mìíràn, òṣìṣẹ́ banki Apapọ …

Ka si »